Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 2:22-24 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sá lọ sí orí òkè, wọ́n sì farapamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí àwọn tí wọn ń lépa wọn fi pada; nítorí pé wọ́n ti wá wọn káàkiri títí ní gbogbo ojú ọ̀nà, wọn kò sì rí wọn.

23. Àwọn ọkunrin meji náà sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ́n lọ bá Joṣua, ọmọ Nuni, wọ́n bá sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un.

24. Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.”

Ka pipe ipin Joṣua 2