Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 19:2-16 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn nìyí: Beeriṣeba, Ṣeba, Molada;

3. Hasari Ṣuali, Bala, Esemu;

4. Elitoladi, Betuli, Horima,

5. Sikilagi, Beti Makabotu, ati Hasari Susa;

6. Beti Lebaotu ati Ṣaruheni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹtala.

7. Enrimoni, Eteri, ati Aṣani, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrin,

8. pẹlu gbogbo àwọn ìletò tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá wọnyi ká títí dé Baalati Beeri, (tí wọ́n ń pè ní Rama) tí ó wà ní Nẹgẹbu ní ìhà gúsù. Òun ni ìpín ti ẹ̀yà Simeoni, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

9. Apá kan ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Simeoni. Ìpín ti ẹ̀yà Juda tóbi jù fún wọn, nítorí náà ni ẹ̀yà Simeoni ṣe mú ninu tiwọn.

10. Ilẹ̀ kẹta tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Sebuluni. Agbègbè tí ó jẹ́ ìpín tiwọn lọ títí dé Saridi.

11. Níbẹ̀ ni ààlà ilẹ̀ wọn ti yípo lọ sókè sí apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì wá sí apá ìlà oòrùn Jokineamu.

12. Láti Saridi, ààlà ilẹ̀ náà lọ sí òdìkejì, ní ìhà ìlà oòrùn, títí dé ààlà Kisiloti Tabori, láti ibẹ̀, ó lọ sí Daberati títí lọ sí Jafia;

13. láti Jafia, ó lọ sí apá ìlà oòrùn títí dé Gati Heferi ati Etikasini, nígbà tí ó dé Rimoni, ó yípo lọ sí apá Nea.

14. Ní apá ìhà àríwá, ààlà náà yípo lọ sí Hanatoni, ó sì pin sí àfonífojì Ifitaeli.

15. Ara àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀ ni, Kata, Nahalali, Ṣimironi, Idala, ati Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila.

16. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Sebuluni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ka pipe ipin Joṣua 19