Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 16:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.

6. Láti ibẹ̀ ó lọ títí dé Òkun Mẹditarenia. Mikimetati ni ààlà wọn ní ìhà àríwá. Ní apá ìlà oòrùn ibẹ̀, ààlà ilẹ̀ wọn yípo lọ sí apá Taanati Ṣilo, ó sì kọjá ibẹ̀ lọ ní ìhà ìlà oòrùn lọ sí Janoa.

7. Lẹ́yìn náà, ní ìsàlẹ̀, láti Janoa, lọ sí Atarotu ati Naara. Ó lọ títí dé Jẹriko, ó sì pin sí odò Jọdani.

8. Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

9. pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu.

10. Ṣugbọn wọn kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Geseri jáde, nítorí náà, àwọn ará Kenaani ń gbé ààrin ẹ̀yà Efuraimu títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Efuraimu ń fi tipátipá mú wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú.

Ka pipe ipin Joṣua 16