orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 16 BIBELI MIMỌ (BM)

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1. Ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Josẹfu bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani lẹ́bàá Jẹriko, ní apá ìlà oòrùn àwọn odò Jẹriko, ó lọ títí dé apá aṣálẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ láti Jẹriko lọ sí apá àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, títí dé Bẹtẹli.

2. Láti Bẹtẹli, ó lọ sí Lusi, ó sì kọjá lọ sí Atarotu, níbi tí àwọn ọmọ Ariki ń gbé.

3. Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

4. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Josẹfu, tí à ń pè ní ẹ̀yà Manase ati ẹ̀yà Efuraimu ṣe gba ìpín tiwọn.

Efuraimu

5. Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.

6. Láti ibẹ̀ ó lọ títí dé Òkun Mẹditarenia. Mikimetati ni ààlà wọn ní ìhà àríwá. Ní apá ìlà oòrùn ibẹ̀, ààlà ilẹ̀ wọn yípo lọ sí apá Taanati Ṣilo, ó sì kọjá ibẹ̀ lọ ní ìhà ìlà oòrùn lọ sí Janoa.

7. Lẹ́yìn náà, ní ìsàlẹ̀, láti Janoa, lọ sí Atarotu ati Naara. Ó lọ títí dé Jẹriko, ó sì pin sí odò Jọdani.

8. Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

9. pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu.

10. Ṣugbọn wọn kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Geseri jáde, nítorí náà, àwọn ará Kenaani ń gbé ààrin ẹ̀yà Efuraimu títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Efuraimu ń fi tipátipá mú wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú.