Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jona 3:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọba Ninefe ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù oyè sílẹ̀, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó ninu eérú.

7. Ó bá ní kí wọn kéde fún àwọn ará Ninefe, pé, “Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ pàṣẹ pé, eniyan tabi ẹranko, tabi ẹran ọ̀sìn kankan kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ, wọn kò sì gbọdọ̀ mu.

8. Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì.

9. A kì í mọ̀, bóyá Ọlọrun lè yí ọkàn rẹ̀ pada, kí ó má jẹ wá níyà mọ́. Bóyá yóo tilẹ̀ dá ibinu rẹ̀ dúró, kò sì ní pa wá run.”

10. Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti pa ìwà burúkú wọn tì, Ọlọrun náà bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, kò sì jẹ wọ́n níyà mọ́.

Ka pipe ipin Jona 3