Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jona 1:13-17 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i.

14. Wọ́n bá gbadura sí OLUWA, wọ́n ní, “A bẹ̀ ọ́, OLUWA, má jẹ́ kí á ṣègbé nítorí ti ọkunrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn; nítorí bí o ti fẹ́ ni ò ń ṣe.”

15. Wọ́n bá gbé Jona jù sinu òkun, òkun sì dákẹ́rọ́rọ́.

16. Ẹ̀rù OLUWA ba àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ lọpọlọpọ, wọ́n rúbọ, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA.

17. OLUWA bá pèsè ẹja ńlá kan tí ó gbé Jona mì. Jona sì wà ninu ẹja náà fún ọjọ́ mẹta.

Ka pipe ipin Jona 1