Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 3:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ogunlọ́gọ̀ wà ní àfonífojì ìdájọ́,nítorí ọjọ́ OLUWA kù sí dẹ̀dẹ̀ níbẹ̀.

15. Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn,àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́.

16. OLUWA kígbe láti Sioni,ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu;ọ̀run ati ayé mì tìtì,ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀,òun ni ibi ààbò fún Israẹli.

17. “Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi.Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́,àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́.

18. “Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà,agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké.Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi.Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA,yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu.

19. “Ijipti yóo di aṣálẹ̀;Edomu yóo sì di ẹgàn,nítorí ìwà ipá tí wọ́n hù sí àwọn ará Juda,nítorí wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ ní ilẹ̀ wọn.

20. Ṣugbọn àwọn eniyan yóo máa gbé ilẹ̀ Juda títí lae,wọn óo sì máa gbé ìlú Jerusalẹmu láti ìrandíran.

21. N óo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ẹ pa, n kò sì ní dá ẹlẹ́bi sí,nítorí èmi OLUWA ni mò ń gbé Sioni.”

Ka pipe ipin Joẹli 3