Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 3:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ẹ ti dòjé bọ oko, nítorí àkókò ìkórè ti tó,ẹ lọ fún ọtí waini nítorí ibi ìfúntí ti kún.Ìkòkò ọtí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀,nítorí ìkà wọ́n pọ̀.

14. Ogunlọ́gọ̀ wà ní àfonífojì ìdájọ́,nítorí ọjọ́ OLUWA kù sí dẹ̀dẹ̀ níbẹ̀.

15. Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn,àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́.

16. OLUWA kígbe láti Sioni,ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu;ọ̀run ati ayé mì tìtì,ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀,òun ni ibi ààbò fún Israẹli.

17. “Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi.Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́,àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́.

18. “Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà,agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké.Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi.Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA,yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu.

Ka pipe ipin Joẹli 3