Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 3:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada,

2. n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati,n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀;nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi.Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi.

3. Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi,wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn,wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó,wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn,wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini.

4. “Kí ni mo fi ṣe yín rí, ẹ̀yin ilẹ̀ Tire, ati ilẹ̀ Sidoni ati gbogbo agbègbè Filistini? Ṣé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan lára mi ni? Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan ni, n óo da ẹ̀san tí ẹ̀ ń gbà le yín lórí kíákíá;

5. nítorí ẹ ti kó fadaka ati wúrà ati àwọn ìṣúra mi olówó iyebíye lọ sí ilé oriṣa yín.

6. Ẹ ta àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu fún àwọn ará Giriki, ẹ kó wọn jìnnà réré sí ilẹ̀ wọn.

7. Ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé wọn dìde níbi tí ẹ tà wọ́n sí, n óo sì gbẹ̀san ìwà yín lára ẹ̀yin alára.

8. N óo ta àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin lẹ́rú fún àwọn ará Juda. Wọn yóo sì tà wọ́n fún àwọn ará Sabea, orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré; nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”

9. Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.Ẹ múra ogun,ẹ rú àwọn akọni sókè.Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí,ogun yá!

10. Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà,ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀,kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.”

Ka pipe ipin Joẹli 3