Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 2:18-32 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19. OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,ẹ óo ní ànítẹ́rùn.N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

20. N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òkú wọn yóo máa rùn;n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.

21. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀,jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,kí o sì máa yọ̀,nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá.

22. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó,nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù,igi gbogbo ti so èso,igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.

23. “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni,kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín;nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò,ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín:ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.

24. Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà,ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀.

25. Gbogbo ohun tí ẹ pàdánùní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín;ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ,gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín.

26. Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn,ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín,tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín,ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

27. Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli;ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́.Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

28. “Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá,n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan,àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrinyín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀,àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá,àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran.

29. Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó,n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín.

30. “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀,n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run,ati sórí ilẹ̀ ayé;yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín.

31. Oòrùn yóo ṣókùnkùn,òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé.

32. Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà.Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni,ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ,àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.

Ka pipe ipin Joẹli 2