Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 2:13-27 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́,kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.”Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín,nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni.Kì í yára bínú,Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.

14. Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada,kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀,kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.

15. Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni,ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ.

16. Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.

17. Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

18. Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19. OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,ẹ óo ní ànítẹ́rùn.N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

20. N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òkú wọn yóo máa rùn;n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.

21. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀,jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,kí o sì máa yọ̀,nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá.

22. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó,nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù,igi gbogbo ti so èso,igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.

23. “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni,kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín;nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò,ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín:ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.

24. Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà,ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀.

25. Gbogbo ohun tí ẹ pàdánùní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín;ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ,gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín.

26. Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn,ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín,tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín,ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

27. Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli;ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́.Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

Ka pipe ipin Joẹli 2