Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 9:23-34 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀,tí ó já sí ikú òjijì,a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn.

24. A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú.Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun,ta ló tún tó bẹ́ẹ̀?

25. “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete,kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn.

26. Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi,bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa.

27. Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi,kí n sì tújúká;kí n má ronú mọ́;

28. ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí,nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀.

29. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi,kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún?

30. Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀,kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́,

31. sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí.Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi.

32. Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi,tí mo fi lè fún un lésì,tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́.

33. Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji,tí ó lè dá wa lẹ́kun.

34. Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀,kí ó má nà mí mọ́!Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́!

Ka pipe ipin Jobu 9