Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 9:14-28 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́?Kí ni kí n sọ?

15. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn.Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú,lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí.

16. Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́,tí ó sì dá mi lóhùn,sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi.

17. Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀,ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí;

18. kò ní jẹ́ kí n mí,ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi.

19. Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni,agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ!Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́,ta ló lè pè é lẹ́jọ́?

20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí;bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀,sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.

21. N kò lẹ́bi,sibẹ n kò ka ara mi kún,ayé sú mi.

22. Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀,nítorí náà ni mo fi wí pé,ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun.

23. Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀,tí ó já sí ikú òjijì,a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn.

24. A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú.Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun,ta ló tún tó bẹ́ẹ̀?

25. “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete,kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn.

26. Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi,bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa.

27. Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi,kí n sì tújúká;kí n má ronú mọ́;

28. ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí,nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Jobu 9