Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 9:10-19 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá,ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà.

11. Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i,ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀.

12. Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà,ta ló lè dá a dúró?Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’

13. “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.

14. Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́?Kí ni kí n sọ?

15. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn.Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú,lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí.

16. Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́,tí ó sì dá mi lóhùn,sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi.

17. Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀,ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí;

18. kò ní jẹ́ kí n mí,ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi.

19. Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni,agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ!Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́,ta ló lè pè é lẹ́jọ́?

Ka pipe ipin Jobu 9