1. Jobu dáhùn pé:
2. “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí,ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?
3. Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn,olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè.
4. Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀,agbára rẹ̀ sì pọ̀.Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ?
5. Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀;tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú.
6. Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀,àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì.