Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 9:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu dáhùn pé:

2. “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí,ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?

3. Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn,olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè.

4. Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀,agbára rẹ̀ sì pọ̀.Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ?

5. Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀;tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú.

6. Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀,àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì.

7. Ó pàṣẹ fún oòrùn,oòrùn kò sì yọ;ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé;

8. òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ,tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.

9. Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run:Beari, Orioni, ati Pileiadesiati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù.

10. Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá,ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà.

11. Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i,ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀.

Ka pipe ipin Jobu 9