Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 5:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Pe ẹnìkan nisinsinyii;ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn?Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ?

2. Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀,owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan.

3. Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀,ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú.

4. Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀,wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè,kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là.

5. Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gúnni ó ti mú un jáde,àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri.

6. Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde.

7. A bí eniyan sinu wahalabí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.

8. “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA,n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́;

9. ẹni tíí ṣe ohun ńlátí eniyan kò lè rídìí,ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà.

10. A máa rọ òjò sórí ilẹ̀,a sì máa bomi rin oko.

11. A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga,a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́.

12. A máa da ète àwọn alárèékérekè rú,kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.

13. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.

Ka pipe ipin Jobu 5