Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 4:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ?Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?

7. “Ìwọ náà ronú wò,ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí?Tabi olódodo kan parun rí?

8. Bí èmi ti rí i sí ni pé,ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè,tí ó sì gbin wahala,yóo kórè ìyọnu.

9. Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run,ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.

10. Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun,ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù,ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.

11. Kinniun alágbára a máa kú,nítorí àìrí ẹran pa jẹ,àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.

12. “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létímo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.

13. Ninu ìran lóru,nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,

14. ìbẹ̀rùbojo mú mi,gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.

15. Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,gbogbo irun ara mi sì dìde.

16. Ó dúró jẹ́ẹ́,ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;gbogbo nǹkan parọ́rọ́,nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,

17. ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?

Ka pipe ipin Jobu 4