Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 4:15-21 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,gbogbo irun ara mi sì dìde.

16. Ó dúró jẹ́ẹ́,ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;gbogbo nǹkan parọ́rọ́,nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,

17. ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?

18. Nígbà tí ó jẹ́ pé,Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀,a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;

19. mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ,tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀,tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.

20. Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́,wọn a parun títí laeláìsí ẹni tí yóo bìkítà.

21. Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀,ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’

Ka pipe ipin Jobu 4