11. Kinniun alágbára a máa kú,nítorí àìrí ẹran pa jẹ,àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.
12. “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létímo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.
13. Ninu ìran lóru,nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,
14. ìbẹ̀rùbojo mú mi,gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.
15. Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,gbogbo irun ara mi sì dìde.
16. Ó dúró jẹ́ẹ́,ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;gbogbo nǹkan parọ́rọ́,nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,
17. ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?
18. Nígbà tí ó jẹ́ pé,Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀,a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;
19. mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ,tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀,tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.