Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 4:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:

2. “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀,ṣé kò ní bí ọ ninu?Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?

3. O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan,o ti fún aláìlera lókun.

4. O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró,ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.

5. Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́,o kò ní sùúrù;Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.

6. Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ?Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?

7. “Ìwọ náà ronú wò,ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí?Tabi olódodo kan parun rí?

8. Bí èmi ti rí i sí ni pé,ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè,tí ó sì gbin wahala,yóo kórè ìyọnu.

9. Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run,ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.

10. Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun,ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù,ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.

11. Kinniun alágbára a máa kú,nítorí àìrí ẹran pa jẹ,àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.

12. “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létímo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.

13. Ninu ìran lóru,nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,

Ka pipe ipin Jobu 4