Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 34:5-19 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi,ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre.

6. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn.

7. “Ta ló dàbí Jobu,tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo,

8. tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn?

9. Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan,ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’

10. “Nítorí náà ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin olóye,Ọlọrun kì í ṣe ibi,Olodumare kì í ṣe ohun tí kò tọ́.

11. Nítorí a máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ati gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.

12. Nítòótọ́, Ọlọrun kì í ṣe ibi,bẹ́ẹ̀ ni Olodumare kì í dájọ́ èké.

13. Ta ló fi í ṣe alákòóso ayé,ta ló sì fi jẹ olórí gbogbo ayé?

14. Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀,

15. gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé,tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀.

16. “Bí ẹ bá ní òye, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ.

17. Ǹjẹ́ ẹni tí ó kórìíra ìdájọ́ ẹ̀tọ́ lè jẹ́ olórí?Àbí ẹ lè dá olódodo ati alágbára lẹ́bi?

18. Ẹni tí ó tó pe ọba ní eniyan lásán,tí ó tó pe ìjòyè ní ẹni ibi;

19. ẹni tí kì í ṣe ojuṣaaju fún àwọn ìjòyè,tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju talaka lọ,nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.

Ka pipe ipin Jobu 34