Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 34:24-37 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Á pa àwọn alágbára run láìṣe ìwádìí wọn,á sì fi àwọn ẹlòmíràn dípò wọn.

25. Nítorí pé ó mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn,á bì wọ́n ṣubú lóru, wọn á sì parun.

26. Á máa jẹ wọ́n níyà ní gbangba,nítorí ìwà ibi wọn.

27. Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé e,wọn kò náání ọ̀nà rẹ̀ kankan,

28. wọ́n ń jẹ́ kí àwọn talaka máa kígbe sí Ọlọrun,a sì máa gbọ́ igbe àwọn tí a ni lára.

29. “Bí Ọlọrun bá dákẹ́,ta ló lè bá a wí?Nígbà tí ó bá fi ojú pamọ́,orílẹ̀-èdè tabi eniyan wo ló lè rí i?

30. Kí ẹni ibi má baà lè ṣe àkóso,kí ó má baà kó àwọn eniyan sinu ìgbèkùn.

31. “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé,‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

32. Kọ́ mi ní ohun tí n kò rí,bí mo bá ti ṣẹ̀ rí, n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́?’

33. Ṣé yóo san ẹ̀san fún ọ lọ́nà tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn,nítorí pé o kọ̀ ọ́?Nítorí ìwọ ni o gbọdọ̀ yan ohun tí ó bá wù ọ́, kì í ṣe èmi,nítorí náà, sọ èrò ọkàn rẹ fún wa.

34. Àwọn tí wọ́n lóye yóo sọ fún mi,àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọn ń gbọ́ mi yóo sọ pẹlu pé,

35. ‘Jobu ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,ó ń sọ̀rọ̀ láìní òye tí ó jinlẹ̀.’

36. À bá lè gbé ọ̀rọ̀ Jobu yẹ̀wò títí dé òpin,nítorí pé ó ń sọ̀rọ̀ bí eniyan burúkú.

37. Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá;ó ń pàtẹ́wọ́ ẹlẹ́yà láàrin wa,ó sì ń kẹ́gàn Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Jobu 34