Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 32:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀.

2. Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun.

3. Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi.

4. Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀.

5. Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i.

6. Ó ní,“Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí,nítorí náà ni ojú fi ń tì mí,tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi.

7. Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀,kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín.

8. Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan,tíí ṣe èémí Olodumare,ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀.

9. Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.

10. Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’

Ka pipe ipin Jobu 32