Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 26:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu bá dáhùn pé,

2. “Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ ti ṣe fún àwọn tí wọn kò lágbára?Aláìlera wo ni ẹ ti gbàlà?

3. Ìmọ̀ràn wo ni ẹ ti fún àwọn aláìgbọ́n?Irú òye wo ni ẹ fihàn wọ́n?

4. Ta ló ń kọ yín ni ohun tí ẹ̀ ń sọ wọnyi?Irú ẹ̀mí wo sì ní ń gba ẹnu yín sọ̀rọ̀?

5. “Àwọn òkú wárìrì nísàlẹ̀.Omi ati àwọn olùgbé inú rẹ̀ pẹlu ń gbọ̀n rìrì.

6. Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun,bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin.

7. Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú,ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú.

8. Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn,sibẹ ìkùukùu kò fà ya.

9. Ó dí ojú òṣùpá,ó sì fi ìkùukùu bò ó.

10. Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi,ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀.

11. Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì,wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀.

12. Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́,nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu.

13. Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́;ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò.

14. Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀,díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀!Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?”

Ka pipe ipin Jobu 26