Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 24:10-23 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀;ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù.

11. Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà,òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn.

12. Àwọn tí wọn ń kú lọ ń kérora ní ìgboro,àwọn tí a pa lára ń ké fún ìrànlọ́wọ́,ṣugbọn Ọlọrun kò fetísí adura wọn.

13. “A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀,tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà.

14. Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde,kí ó lè pa talaka ati aláìní,a sì dàbí olè ní òru.

15. Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú,ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’;ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.

16. Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri,ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́,wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí,wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀.

17. Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn,ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.”

18. Sofari dáhùn pé,“O sọ wí pé,‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá;ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà,ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.

19. Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹbẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì.

20. Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú,ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’

21. Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ,wọn kò sì ṣe rere fún opó.

22. Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀;wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn.

23. Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́,ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn.

Ka pipe ipin Jobu 24