Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 24:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Kí ló dé tí Olodumare kò fi yan ọjọ́ ìdájọ́,kí àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n sì rí ọjọ́ náà?

2. “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò,láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn,wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn.

3. Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ,wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.

4. Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́.

5. “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri,bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀,wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀.

6. Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olókowọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà.

7. Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru,wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù.

8. Òjò a pa wọ́n lórí òkè,wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò.

9. (Àwọn kan ń já àwọn ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú,wọ́n sì ń gba ọmọ ọwọ́ lọ́wọ́ àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.)

10. Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀;ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù.

11. Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà,òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn.

Ka pipe ipin Jobu 24