Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 12:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu dáhùn pé:

2. “Láìsí àní àní,ẹ̀yin ni agbẹnusọ gbogbo eniyan,bí ẹ bá jáde láyé,ọgbọ́n kan kò tún ní sí láyé mọ́.

3. Bí ẹ ti ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ní,ẹ kò sàn jù mí lọ.Ta ni kò mọ irú nǹkan, tí ẹ̀ ń sọ yìí?

4. Mo wá di ẹlẹ́yà lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi,èmi tí mò ń ké pe Ọlọrun,tí ó sì ń dá mi lóhùn;èmi tí mo jẹ́ olódodo ati aláìlẹ́bi,mo wá di ẹlẹ́yà.

5. Lójú ẹni tí ara tù,ìṣòro kì í báni láìnídìí.Lójú rẹ̀, ẹni tí ó bá ṣìṣe ni ìṣòro wà fún.

6. Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia,àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu,àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn.

Ka pipe ipin Jobu 12