Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 6:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà!Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa,kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu,nítorí pé nǹkan burúkúati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá.

2. Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà,ṣugbọn n óo pa á run.

3. Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú,wọn yóo pa àgọ́ yí i ká,ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú.

4. Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun;ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!”Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ,ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú!

5. Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru;kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!”

6. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé:“Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀;kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í.Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà,nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀.

7. Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga,bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu.Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀,àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.

8. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà,n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro,ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.”

Ka pipe ipin Jeremaya 6