Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 50:43-46 BIBELI MIMỌ (BM)

43. Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn,ọwọ́ rẹ̀ rọ,ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí.

44. “Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

45. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn.

46. Ariwo wíwó odi Babiloni yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.”

Ka pipe ipin Jeremaya 50