Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 5:7-14 BIBELI MIMỌ (BM)

7. OLUWA bi Israẹli pé,“Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra.Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán,wọ́n ṣe àgbèrè,wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè.

8. Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó,olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri.

9. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?

10. Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run,ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán.Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA.

11. Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12. Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA,wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan;ibi kankan kò ní dé bá wa,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.”

13. Àwọn wolii yóo di àgbá òfo;nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn.Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn.

14. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,iná yóo sì jó wọn run.

Ka pipe ipin Jeremaya 5