Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 5:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”

20. OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda:

21. Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n,ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran;ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn.

22. Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín?Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè.Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun,tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé!Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan,kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.

23. Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín.Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ.

24. Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé:‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa,tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀,ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn;OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́,tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’

25. Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada,ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín.

26. “Àwọn eniyan burúkú wà láàrin àwọn eniyan mi,wọ́n ń dọdẹ eniyan bí ẹni dọdẹ ẹyẹ,wọ́n dẹ tàkúté, wọ́n fi ń mú eniyan.

27. Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀,bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ.Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá,wọ́n di olówó,

28. wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán.Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà.Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba,kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà;wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní,kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́.

29. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí?

30. Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu,ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:

31. Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin,àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”

Ka pipe ipin Jeremaya 5