Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 44:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nǹkan tí Jeremaya gbọ́ nípa gbogbo àwọn Juu tí wọn ń gbé Migidoli ati Tapanhesi, ati Memfisi ati ilẹ̀ Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti nìyí.

2. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Ẹ rí gbogbo ibi tí mo jẹ́ kí ó bá Jerusalẹmu ati gbogbo ìlú Juda. Ẹ wò wọ́n lónìí bí wọ́n ti di ahoro, tí kò sì sí eniyan ninu wọn,

3. nítorí ibi tí wọ́n ṣe, wọ́n mú mi bínú nítorí pé wọ́n sun turari sí àwọn oriṣa tí àwọn tabi àwọn baba wọn kò mọ̀ rí, wọ́n sì ń sìn wọ́n.

4. Sibẹsibẹ mo rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, sí wọn, kí wọ́n sọ fún wọn pé kí wọn má ṣe ohun ìríra tí n kò fẹ́.

5. Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò fetí sílẹ̀, wọn kò dáwọ́ ibi ṣíṣe dúró, wọn kò sì yé sun turari sí oriṣa mọ́.

6. Mo bá bínú gan-an sí àwọn ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu; mo sì sọ wọ́n di aṣálẹ̀ ati ahoro bí wọ́n ti wà lónìí.

7. “Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli wá ń bi yín léèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ara yín ní ibi tó báyìí? Ṣé ẹ fẹ́ kó gbogbo àwọn eniyan wọnyi kúrò ní ilẹ̀ Juda, ati àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àtọmọ ọmú, àtọmọ ọwọ́, títí tí kò fi ní ku ẹnikẹ́ni ninu yín lẹ́yìn ni?

8. Kí ló dé tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bí mi ninu, tí ẹ̀ ń sun turari sí àwọn oriṣa ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ̀ ń gbé? Ṣé ẹ fẹ́ kí n pa yín run, kí ẹ di ẹni ẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni ẹ ṣe ń ṣe báyìí?

9. Ṣé ẹ ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín ṣe ní ilẹ̀ Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí àwọn ọba Juda ati àwọn ayaba ṣe ati ẹ̀yin pẹlu àwọn iyawo yín?

10. Wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ títí di òní, tabi kí wọn bẹ̀rù, tabi kí wọ́n pa òfin ati ìlànà tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín mọ́.’

11. “Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ wò ó, n óo dójúlé yín, n óo sì pa gbogbo ọmọ Juda run.

Ka pipe ipin Jeremaya 44