Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 40:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, tú u sílẹ̀ ní Rama. Nebusaradani rí Jeremaya tí wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì kó o pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn kó kúrò ní ìlú Jerusalẹmu ati ní ilẹ̀ Juda tí wọn ń kó lọ sí Babiloni.

2. Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, sọ fún Jeremaya pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ti pinnu láti ṣe ilẹ̀ yìí ní ibi;

3. Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín.

4. Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ.

Ka pipe ipin Jeremaya 40