Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 36:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó ṣeéṣe kí wọn mú ẹ̀bẹ̀ wọn wá siwaju OLUWA, kí olukuluku sì yipada kúrò lọ́nà ibi rẹ̀ tí ó ń rìn, nítorí pé ibinu OLUWA pọ̀ lórí wọn.”

8. Baruku bá ṣe gbogbo ohun tí Jeremaya wolii pa láṣẹ fún un lati kà lati inú ìwé ilé Oluwa.

9. Ní oṣù kẹsan-an, ọdún karun-un tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba ní Juda, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn eniyan tí wọ́n ti àwọn ìlú Juda wá sí Jerusalẹmu, kéde ọjọ́ ààwẹ̀ níwájú OLUWA.

10. Baruku bá ka ọ̀rọ̀ Jeremaya tí ó kọ sinu ìwé, sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan ní yàrá Gemaraya, ọmọ Ṣafani, akọ̀wé, tí ó wà ní gbọ̀ngàn òkè ní Ẹnu Ọ̀nà Titun ilé OLUWA.

11. Nígbà tí Mikaaya ọmọ Gemaraya, ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA tí ó wà ninu ìwé náà;

12. Ó lọ sí yàrá akọ̀wé ní ààfin ọba, ó bá gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn jókòó níbẹ̀: Eliṣama akọ̀wé ati Delaaya ọmọ Ṣemaaya, ati Elinatani ọmọ Akibori, ati Gemaraya ọmọ Ṣafani, ati Sedekaya ọmọ Hananaya ati gbogbo àwọn ìjòyè.

13. Mikaaya sọ gbogbo ohun tí ó gbọ́, nígbà tí Baruku ka ohun tí ó kọ sinu ìwé fún wọn.

14. Gbogbo àwọn ìjòyè bá rán Jehudi ọmọ Netanaya, ọmọ Ṣelemaya ọmọ Kuṣi pé kí ó lọ sọ fún Baruku kí ó máa bọ̀ kí ó sì mú ìwé tí ó kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́. Baruku, ọmọ Neraya, sì wá sọ́dọ̀ wọn tòun ti ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀.

15. Wọ́n ní kí ó jókòó, kí ó kà á fún àwọn, Baruku bá kà á fún wọn.

16. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú. Wọ́n bá sọ fún Baruku pé, “A gbọdọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.”

17. Wọ́n bi Baruku pé, “Sọ fún wa, báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀? Ṣé Jeremaya ni ó sọ ọ́, tí ìwọ fi ń kọ ọ́ ni, àbí báwo?”

Ka pipe ipin Jeremaya 36