Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 36:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé.

19. Àwọn ìjòyè bá sọ fún Baruku pé kí òun ati Jeremaya lọ sápamọ́, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí wọ́n wà.

20. Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.

21. Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

22. Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada.

23. Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán.

24. Sibẹ ẹ̀rù kò ba ọba tabi àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò sì fa aṣọ wọn ya.

25. Elinatani, Dilaaya ati Gemaraya tilẹ̀ bẹ ọba pé kí ó má fi ìwé náà jóná, ṣugbọn kò gbà.

26. Ọba bá pàṣẹ fún Jerameeli ọmọ rẹ̀, ati Seraaya ọmọ Asirieli, ati Ṣelemaya ọmọ Abideeli, pé kí wọn lọ mú Baruku akọ̀wé, ati Jeremaya wolii wá, ṣugbọn OLUWA fi wọ́n pamọ́.

27. Lẹ́yìn tí ọba ti fi ìwé náà jóná, ati gbogbo ohun tí Jeremaya ní kí Baruku kọ sinu rẹ̀, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

28. “Mú ìwé mìíràn kí o tún kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé ti àkọ́kọ́, tí Jehoiakimu, ọba Juda fi jóná sinu rẹ̀.

29. Ohun tí o óo kọ nípa Jehoiakimu ọba Juda, nìyí: sọ pé èmi OLUWA ní, ṣé ó fi ìwé ti àkọ́kọ́ jóná ni, ó ní, kí ló dé tí a fi kọ sinu rẹ̀ pé dájúdájú, ọba Babiloni ń bọ̀ wá pa ilẹ̀ yìí run ati pé, yóo pa ati eniyan ati ẹranko tí ó wà ninu rẹ̀ run?

Ka pipe ipin Jeremaya 36