Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 36:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Wọ́n ní kí ó jókòó, kí ó kà á fún àwọn, Baruku bá kà á fún wọn.

16. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú. Wọ́n bá sọ fún Baruku pé, “A gbọdọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.”

17. Wọ́n bi Baruku pé, “Sọ fún wa, báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀? Ṣé Jeremaya ni ó sọ ọ́, tí ìwọ fi ń kọ ọ́ ni, àbí báwo?”

18. Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé.

19. Àwọn ìjòyè bá sọ fún Baruku pé kí òun ati Jeremaya lọ sápamọ́, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí wọ́n wà.

20. Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.

21. Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

22. Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada.

Ka pipe ipin Jeremaya 36