Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 33:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ó ní, “Àkókò ń bọ̀, tí n óo mú ìlérí tí mo ṣe fún ilé Israẹli ati ilé Juda ṣẹ.

15. Nígbà tó bá yá, tí àkókò bá tó, n óo mú kí ẹ̀ka òdodo kan ó sọ jáde ní ilé Dafidi, yóo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo ní ilẹ̀ náà.

16. A óo gba Juda là, Jerusalẹmu yóo sì wà ní àìléwu, orúkọ tí a óo wá máa pè é ni ‘OLÚWA ni Òdodo wa.’ ”

17. Nítorí OLUWA ní kò ní sí ìgbà kan, tí kò ní jẹ́ pé ọkunrin kan ní ilé Dafidi ni yóo máa jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli,

18. bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní sí ìgbà kan tí ẹnìkan ninu àwọn alufaa, ọmọ Lefi, kò ní máa dúró níwájú òun láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, láti máa rú ẹbọ títí lae.

19. OLUWA tún bá Jeremaya sọ̀rọ̀;

20. ó ní, “Bí ẹ bá lè ba majẹmu tí mo bá ọ̀sán ati òru dá jẹ́, tí wọn kò fi ní wà ní àkókò tí mo yàn fún wọn mọ́,

21. òun nìkan ni majẹmu tí mo bá Dafidi iranṣẹ mi dá ṣe lè yẹ̀, tí ìdílé rẹ̀ kò fi ní máa ní ọmọkunrin kan tí yóo jọba; bẹ́ẹ̀ náà ni majẹmu tí mo bá àwọn alufaa, ọmọ Lefi iranṣẹ mi dá.

22. Bí a kò ti ṣe lè ka iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí a kò sì lè wọn yanrìn etí òkun, bẹ́ẹ̀ ní n óo ṣe sọ arọmọdọmọ Dafidi ati arọmọdọmọ Lefi alufaa, iranṣẹ mi, di pupọ.”

Ka pipe ipin Jeremaya 33