Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 31:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,n óo kó wọn jọ láti òpin ayé.Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn,ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́.Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí.

9. Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá,tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada.N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn,lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ;nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.”

10. OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré;ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ,yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’

11. Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada,yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ.

12. Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni,wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn:Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró,ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù;ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́.

13. Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà,àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá.N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn.

14. N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ,n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 31