Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 31:22-33 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ìgbà wo ni ẹ óo ṣe iyèméjì dà, ẹ̀yin alainigbagbọ wọnyi?Nítorí OLUWA ti dá ohun titun sórí ilẹ̀ ayé,bíi kí obinrin máa dáàbò bo ọkunrin.”

23. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé,‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu,ibùgbé olódodo.’

24. Àwọn eniyan yóo máa gbé àwọn ìlú Juda ati àwọn agbègbè rẹ̀ pẹlu àwọn àgbẹ̀ ati àwọn darandaran.

25. Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.”

26. Lẹ́sẹ̀ kan náà mo tají, mo wò yíká, oorun tí mo sùn sì dùn mọ́ mi.

27. OLUWA ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo kó àtènìyàn, àtẹranko kún ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Juda.

28. Nígbà tí àkókò bá tó, gẹ́gẹ́ bí mo tí ń ṣọ́ wọn tí mo fi fà wọ́n tu, tí mo wó wọn lulẹ̀, tí mo bì wọ́n wó, tí mo pa wọ́n run, tí mo sì mú kí ibi ó bá wọn; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣọ́ wọn tí n óo fi kọ́ àwọn ìlú wọn tí n óo sì fìdí wọn múlẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

29. Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé,‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan,àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’

30. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan,òun ni eyín yóo kan.Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.

31. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun.

32. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn.

33. Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi.

Ka pipe ipin Jeremaya 31