Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 30:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.”

4. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa Israẹli ati Juda nìyí:

5. “A ti gbọ́ igbe ìdágìrì ati ti ẹ̀rù,kò sì sí alaafia.

6. Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí;ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ?Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin,tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí?Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro?

7. Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà yóo jẹ́,kò sí ọjọ́ tí yóo dàbí rẹ̀,àkókò ìpọ́njú ni yóo jẹ́ fún ilé Jakọbu;ṣugbọn wọn yóo bọ́ ninu rẹ̀.”

8. OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá,n óo já àjàgà kúrò lọ́rùn wọn.N óo já ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi so wọ́n,wọn kò sì ní ṣe iranṣẹ fún àjèjì mọ́.

9. Ṣugbọn wọn yóo máa sin Ọlọrun wọn,ati ti Dafidi, ọba wọn, tí n óo gbé dìde fún wọn.

10. “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin eniyan Jakọbu, iranṣẹ mi,ẹ má sì jẹ́ kí àyà fò yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N óo ti òkèèrè wá gbà yín là,N óo gba àwọn ọmọ yín tí wọ́n wà ní ìgbèkùn là pẹlu.Àwọn ọmọ Jakọbu yóo pada ní ìfọ̀kànbalẹ̀ ati ìrọ̀rùn,ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.

11. Nítorí pé mo wà pẹlu yín, n óo gbà yín là.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n óo pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo fọn yín ká sí ni n óo parun patapata,ṣugbọn n kò ní pa ẹ̀yin run.N óo jẹ yín níyà,ṣugbọn n kò ní fi ìyà tí kò tọ́ jẹ yín.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 30