Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 30:20-24 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́,àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi.N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára.

21. Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn,ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn;n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi,nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì jẹ́ Ọlọrun yín.”

23. Ẹ wo ìjì OLUWA!Ibinu rẹ̀ ń bọ̀ bí ìjì líle.Ó ń bọ̀ sórí àwọn oníṣẹ́ ibi.

24. Ibinu gbígbóná OLUWA kò ní yipada,títí yóo fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Òye nǹkan wọnyi yóo ye yín ní ọjọ́ ìkẹyìn.

Ka pipe ipin Jeremaya 30