Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 3:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀,tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ,tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn,ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada?Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́?Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́;ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi?

2. Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká,ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé?Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà,bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀.Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́.

3. Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀,tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ.Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó,ojú kò sì tì yín.

4. Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé,‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

5. Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni?Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀,ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.”

6. OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù?

Ka pipe ipin Jeremaya 3