Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 29:24-32 BIBELI MIMỌ (BM)

24. OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé,

25. “Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé:

26. “Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn.

27. Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí.

28. Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.”

29. Sefanaya Alufaa ka ìwé náà sí etí Jeremaya wolii.

30. OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé,

31. “Ranṣẹ sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn wí pé ohun tí OLUWA wí nípa Ṣemaaya ará Nehelamu ni pé: nítorí pé Ṣemaaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí òun kò rán an, ó sì mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ èké,

32. òun OLUWA óo fìyà jẹ Ṣemaaya ará Nehelamu náà ati ìran rẹ̀; kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo wà láàyè láàrin àwọn eniyan rẹ̀ láti fojú rí nǹkan rere tí n óo ṣe fún àwọn eniyan mi, nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”

Ka pipe ipin Jeremaya 29