Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 29:11-28 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí.

12. Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín.

13. Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi.

14. Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15. “Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’

16. Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn,

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’

18. Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ.

19. Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo.

20. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’

21. “Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín.

22. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’

23. nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.”

24. OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé,

25. “Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé:

26. “Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn.

27. Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí.

28. Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 29