Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 26:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, ọmọ Josaya,

2. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́.

3. Ó ṣeéṣe kí wọ́n gbọ́, kí olukuluku wọn sì yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀; kí n lè yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo fẹ́ ṣe sí wọn nítorí iṣẹ́ burúkú wọn.

4. “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA ní bí wọn kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, kí wọn máa pa òfin tí mo gbé kalẹ̀ fún wọn mọ́,

5. kí wọn sì máa gbọ́ràn sí àwọn iranṣẹ mi lẹ́nu, ati àwọn wolii mi tí mò ń rán sí wọn léraléra, bí wọn kò tilẹ̀ kà wọ́n sí,

6. nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.”

7. Àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan gbọ́ tí Jeremaya ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilé OLUWA.

8. Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú!

9. Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA.

10. Nígbà tí àwọn ìjòyè Juda gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lọ sí ilé OLUWA láti ààfin ọba, wọ́n sì jókòó ní Ẹnu Ọ̀nà Titun tí ó wà ní ilé OLUWA.

11. Àwọn alufaa ati àwọn wolii bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “Ẹjọ́ ikú ni ó yẹ kí a dá fún ọkunrin yìí nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ń sọ nípa ìlú yìí, ẹ̀yin náà sá fi etí ara yín gbọ́.”

Ka pipe ipin Jeremaya 26