Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 25:32-38 BIBELI MIMỌ (BM)

32. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ibi yóo máa ṣẹlẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, ìjì ńlá yóo sì jà láti òpin ayé wá.

33. Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀.

34. Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa.

35. Kò ní sí ààbò mọ́ fún àwọn olùṣọ́-aguntan, kò ní sí ọ̀nà ati sá àsálà fún àwọn oluwa àwọn agbo ẹran.

36. Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-aguntanati ẹkún ẹ̀dùn ti àwọn oluwa agbo ẹran;nítorí OLUWA ń ba ibùjẹ ẹran wọn jẹ́.

37. Pápá oko tútù tí ìbẹ̀rù kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di ahoronítorí ibinu gbígbóná OLUWA.

38. Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀,ilẹ̀ wọn sì ti di ahoronítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA.

Ka pipe ipin Jeremaya 25