Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 24:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni ti kó Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu kúrò ní ìlú Jerusalẹmu lọ sí Babiloni, pẹlu àwọn ìjòyè Juda, ati àwọn oníṣẹ́ ọnà, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, OLUWA fi ìran yìí hàn mí. Mo rí apẹ̀rẹ̀ èso ọ̀pọ̀tọ́ meji níwájú ilé OLUWA.

2. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ kinni dára gbáà, ó dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kọ́kọ́ pọ́n. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ keji ti rà patapata tóbẹ́ẹ̀ tí kò ṣe é jẹ. p

3. OLUWA bá bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí?”Mo ní, “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni, àwọn tí ó dára, dára gan-an, àwọn tí kò sì dára bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣe é jẹ.”

4. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

Ka pipe ipin Jeremaya 24