Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 22:9-16 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ majẹmu OLUWA Ọlọrun wọn sílẹ̀ ni, wọ́n ń bọ oriṣa, wọ́n sì ń sìn wọ́n.’ ”

10. Ẹ̀yin ará Juda,ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú,ẹ má sì dárò rẹ̀.Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún,nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí.

11. Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́.

12. Ibi tí wọn mú un ní ìgbèkùn lọ ni yóo kú sí; kò ní fi ojú rí ilẹ̀ yìí mọ́.”

13. Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé,tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀.Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́,láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un.

14. Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé,“N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi,ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.”Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́.Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀,ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún.

15. Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba?Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni,tabi kò rí mu?Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo,ṣebí ó sì dára fún un.

16. Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní,ohun gbogbo sì ń lọ dáradára.Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA?OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 22