Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 22:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún mi pé, kí n lọ sí ilé ọba Juda kí n sọ fún un níbẹ̀ pé,

2. “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé:

3. Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí.

4. Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan.

5. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí mo wí, mo ti fi ara mi búra pé ilẹ̀ yìí yóo di ahoro. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

6. OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé,“Bíi Gileadi ni o dára lójú mi,ati bí orí òkè Lẹbanoni.Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀;o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé.

7. N óo kó àwọn apanirun tí yóo pa ọ́ run wá,olukuluku yóo wá pẹlu ohun ìjà rẹ̀.Wọn óo gé àwọn tí wọn dára jùlọ ninu àwọn igi Kedari yín,wọn óo sì sun wọ́n níná.

8. “Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo máa gba ìlú yìí kọjá; wọn yóo sì máa bi ara wọn pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ìlú ńlá yìí?’

9. Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ majẹmu OLUWA Ọlọrun wọn sílẹ̀ ni, wọ́n ń bọ oriṣa, wọ́n sì ń sìn wọ́n.’ ”

10. Ẹ̀yin ará Juda,ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú,ẹ má sì dárò rẹ̀.Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún,nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí.

Ka pipe ipin Jeremaya 22